1. Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí.
2. OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?”OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu?
3. Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.”