Maku 4:25-40 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nítorí ẹni tí ó bá ní, a óo tún fi fún un sí i; ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.”

26. Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko;

27. ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀.

28. Ilẹ̀ fúnra ara rẹ̀ ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn so èso: yóo kọ́ rú ewé, lẹ́yìn náà èso rẹ̀ yóo gbó.

29. Nígbà tí ó bá gbó tán, lẹsẹkẹsẹ ọkunrin náà yóo yọ dòjé jáde nítorí pé àkókò ìkórè ti dé.”

30. Ó tún bèèrè pé, “Báwo ni à bá ṣe ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun, tabi òwe wo ni à bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?”

31. Ó ní, “Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn,

32. ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.”

33. Pẹlu ọpọlọpọ irú òwe bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn, gẹ́gẹ́ bí òye wọn ti mọ láti lè gbọ́.

34. Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a máa túmọ̀ gbogbo rẹ̀ fún wọn.

35. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.”

36. Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu.

37. Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀.

38. Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!”

39. Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé.

40. Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?”

Maku 4