Maku 4:22-29 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba.

23. Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”

24. Ó tún wí fún wọn pé, “Ẹ fi ara balẹ̀ ro ohun tí ẹ bá gbọ́. Irú òfin tí ẹ bá fi ń ṣe ìdájọ́ fún eniyan ni a óo fi ṣe ìdájọ́ fún ẹ̀yin náà pẹlu èlé.

25. Nítorí ẹni tí ó bá ní, a óo tún fi fún un sí i; ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.”

26. Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko;

27. ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀.

28. Ilẹ̀ fúnra ara rẹ̀ ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn so èso: yóo kọ́ rú ewé, lẹ́yìn náà èso rẹ̀ yóo gbó.

29. Nígbà tí ó bá gbó tán, lẹsẹkẹsẹ ọkunrin náà yóo yọ dòjé jáde nítorí pé àkókò ìkórè ti dé.”

Maku 4