Maku 3:31-35 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Nígbà tí ó yá ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n bá ranṣẹ pè é.

32. Àwọn eniyan jókòó yí i ká, wọ́n bá sọ fún un pé, “Gbọ́ ná, ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ ń bèèrè rẹ lóde.”

33. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi ati arakunrin mi?”

34. Nígbà tí ó wo gbogbo àwọn tí ó jókòó yí i ká lọ́tùn-ún lósì, ó ní, “Ẹ̀yin ni ìyá mi ati arakunrin mi.

35. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, òun ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati ìyá mi.”

Maku 3