1. Jesu tún wọ inú ilé ìpàdé lọ. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.
2. Àwọn kan wà tí wọn ń ṣọ́ ọ bí yóo wo ọkunrin yìí sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, kí wọn lè fi í sùn.
3. Ó wí fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde dúró ní ààrin àwùjọ.”
4. Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?”Ṣugbọn wọn kò fọhùn.
5. Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.
6. Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á.