Maku 16:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́.

14. Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.

15. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.

16. Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi.

17. Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀;

18. wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.”

Maku 16