Maku 15:28-33 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”]

29. Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta,

30. gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.”

31. Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là.

32. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.”Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú.

33. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán.

Maku 15