1. Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́.
2. Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”
3. Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án.
4. Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?”
5. Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu.
6. Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀.
7. Ẹnìkan wà tí ó ń jẹ́ Baraba, tí ó wà ninu ẹ̀wọ̀n pẹlu àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tí wọ́n pa eniyan ní àkókò ọ̀tẹ̀.
8. Àwọn eniyan bá gòkè tọ Pilatu lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn.
9. Pilatu wá bi wọ́n pé, “Ẹ fẹ́ kí n dá ọba àwọn Juu sílẹ̀ fun yín bí?”
10. Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí alufaa ń jowú Jesu, wọ́n sì ń ṣe kèéta rẹ̀, ni wọ́n ṣe fà á wá siwaju òun.
11. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa rú àwọn eniyan sókè pé Baraba ni kí ó kúkú dá sílẹ̀ fún wọn.
12. Pilatu tún bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní ọba àwọn Juu?”
13. Nígbà náà ni gbogbo wọn kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”
14. Ṣugbọn Pilatu bi wọ́n pé, “Nítorí kí ni? Nǹkan burúkú wo ni ó ṣe?”Ṣugbọn wọ́n sá tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”