Maku 13:34-36 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.

35. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú.

36. Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun.

Maku 13