Maku 1:28-30 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili.

29. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu.

30. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀.

Maku 1