Luku 9:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá ń lọ láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń waasu ìyìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.

7. Nígbà tó yá, Hẹrọdu, baálẹ̀, gbọ́ nípa gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó dààmú; nítorí àwọn kan ń sọ pé Johanu ni ó jí dìde kúrò ninu òkú.

8. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé Elija ni ó fara hàn. Àwọn mìíràn ní ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó tún pada.

9. Ṣugbọn Hẹrọdu ní “Ní ti Johanu, mo ti bẹ́ ẹ lórí. Ta wá ni òun, tí mò ń gbọ́ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀?” Hẹrọdu bá ń wá ọ̀nà láti fojú kàn án.

10. Àwọn aposteli tí Jesu rán níṣẹ́ pada wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún un. Ó bá rọra dá àwọn nìkan mú lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Bẹtisaida.

11. Ṣugbọn àwọn eniyan mọ̀, ni wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó gbà wọ́n pẹlu ayọ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo àwọn aláìsàn sàn.

Luku 9