19. Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.”
20. Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?”Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.”
21. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni.
22. Ó ní, “Dandan ni kí Ọmọ-Eniyan jìyà pupọ, kí àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin kọ̀ ọ́, kí wọ́n sì pa á, ṣugbọn a óo jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”
23. Ó bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀lé mí, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀ lojoojumọ, kí ó wá máa tọ̀ mí lẹ́yìn.