Luku 9:15-29 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí: wọ́n fi gbogbo wọn jókòó.

16. Jesu bá mú burẹdi marun-un yìí ati ẹja meji, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó gbadura sí i, ó pín wọn sí wẹ́wẹ́, ó bá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fún àwọn eniyan.

17. Gbogbo àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n kó àjẹkù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.

18. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?”

19. Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.”

20. Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?”Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.”

21. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni.

22. Ó ní, “Dandan ni kí Ọmọ-Eniyan jìyà pupọ, kí àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin kọ̀ ọ́, kí wọ́n sì pa á, ṣugbọn a óo jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”

23. Ó bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀lé mí, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀ lojoojumọ, kí ó wá máa tọ̀ mí lẹ́yìn.

24. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, òun ni yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

25. Nítorí anfaani wo ni ó jẹ́ fún ẹnikẹ́ni, bí ó bá jèrè gbogbo ayé, ṣugbọn tí ó pàdánù ẹ̀mí ara rẹ̀?

26. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi ati àwọn ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ-Eniyan yóo tijú nígbà tí ó bá dé ninu ògo rẹ̀ ati ògo Baba rẹ̀, pẹlu àwọn angẹli mímọ́.

27. Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.”

28. Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura.

29. Bí ó ti ń gbadura, ìwò ojú rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ wá funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Luku 9