Luku 4:38-41 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu.

39. Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn.

40. Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn.

41. Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.

Luku 4