29. “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’
30. Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ náà ní, ‘Ó tì, Abrahamu, Baba! Bí ẹnìkan bá jí dìde ninu òkú, tí ó lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóo ronupiwada.’
31. Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ”