Luku 12:43-47 BIBELI MIMỌ (BM)

43. Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé.

44. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní.

45. Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó,

46. ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ.

47. “Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.

Luku 12