Luku 11:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò.

9. “Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.

10. Nítorí gbogbo ẹni tí ó bá bèèrè ni yóo rí gbà; ẹni tí ó bá wá kiri yóo rí; ẹni tí ó bá sì kan ìlẹ̀kùn ni a óo ṣí i fún.

11. Baba wo ninu yín ni ó jẹ́ fún ọmọ rẹ̀ ní ejò, nígbà tí ọmọ bá bèèrè ẹja?

12. Tabi bí ó bá bèèrè ẹyin tí ó jẹ́ fún un ní àkeekèé?

13. Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”

14. Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan.

15. Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

Luku 11