41. Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín.
42. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà.
43. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà.
44. Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”
45. Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!”