Luku 1:65-73 BIBELI MIMỌ (BM)

65. Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo àwọn aládùúgbò wọn. Ìròyìn tàn ká gbogbo agbègbè olókè Judia, wọ́n ń sọ ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀.

66. Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ń da ọ̀rọ̀ náà rò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń sọ pé, “Irú ọmọ wo ni èyí yóo jẹ́?” Nítorí ọwọ́ Oluwa wà lára rẹ̀.

67. Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé,

68. Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹlinítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀,ó sì ti dá wọn nídè.

69. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún waní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀;

70. gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́,láti ọjọ́ pípẹ́;

71. pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá waati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;

72. pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò,ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́

73. gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa,

Luku 1