28. Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára.
29. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ alufaa tí ó bá jẹ́ ọkunrin lè jẹ ninu ohun ìrúbọ yìí; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.
30. Ṣugbọn bí wọ́n bá mú ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu Àgọ́ Àjọ, tí wọ́n bá lò ó fún ètùtù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran náà, sísun ni wọ́n gbọdọ̀ sun ún.