Lefitiku 6:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. “Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́.

21. Kí wọ́n fi òróró po ìyẹ̀fun náà dáradára, kí wọ́n tó yan án lórí ààrò, lẹ́yìn náà kí wọ́n rún un gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọ́n sì fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

22. Ẹni tí wọ́n bá yàn sí ipò olórí alufaa lẹ́yìn Aaroni ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo máa rú ẹbọ yìí sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí ìlànà títí lae, gbogbo ìyẹ̀fun náà ni yóo fi rú ẹbọ sísun.

23. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ninu ìyẹ̀fun ẹbọ ohun jíjẹ ti alufaa, gbogbo rẹ̀ ni kí wọ́n fi rú ẹbọ sísun.”

24. OLUWA sọ fún Mose pé,

25. “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran fún ẹbọ sísun, ni kí wọ́n ti máa pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ pẹlu, níwájú OLUWA; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.

26. Alufaa tí ó bá fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo jẹ ẹ́; níbi mímọ́, ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni kí ó ti jẹ ẹ́.

27. Ohunkohun tí ó bá ti kan ẹran rẹ̀ di mímọ́; nígbà tí wọ́n bá sì ta lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára aṣọ kan, ibi mímọ́ ni wọ́n ti gbọdọ̀ fọ aṣọ náà.

28. Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára.

Lefitiku 6