Lefitiku 5:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.

8. Kí ó kó wọn wá sọ́dọ̀ alufaa, kí alufaa sì fi ekinni rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lílọ́ ni kí alufaa lọ́ ọ lọ́rùn, ṣugbọn kí ó má fà á lọ́rùn tu.

9. Kí alufaa wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara pẹpẹ, kí ó ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.

10. Lẹ́yìn náà yóo fi ẹyẹ keji rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.

11. “Ṣugbọn bí kò bá ní agbára láti mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji wá, ohun tí yóo mú wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni, ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ó má fi òróró tabi turari olóòórùn dídùn sórí rẹ̀, nítorí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Lefitiku 5