10. (gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń yọ wọ́n lára mààlúù tí wọn ń fi rú ẹbọ alaafia), yóo sì sun wọ́n níná lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.
11. Ṣugbọn awọ akọ mààlúù náà, ati gbogbo ẹran rẹ̀ ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ati nǹkan inú rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀;
12. pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀.
13. “Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi,