1. OLUWA ní kí Mose
2. sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí:
3. “Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.
4. Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA.