Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín.