6. Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.
7. Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
8. Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́.
9. Ọmọ alufaa lobinrin, tí ó bá sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe àgbèrè káàkiri, sọ baba rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí náà sísun ni kí ẹ dáná sun ọmọ náà.
10. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ alufaa àgbà láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n ti ta òróró sí lórí láti yà á sọ́tọ̀, kí ó lè máa wọ àwọn aṣọ mímọ́, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ rí játijàti; kò sì gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya, láti fi hàn pé ó ń ṣọ̀fọ̀.