1. OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ikú àwọn eniyan rẹ̀.
2. Àfi ti àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ wọn, bíi ìyá tabi baba rẹ̀; tabi ọmọ tabi arakunrin rẹ̀,
3. tabi ti arabinrin rẹ̀ tí kò tíì mọ ọkunrin, (tí ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí pé kò tíì ní ọkọ, nítorí tirẹ̀, alufaa náà lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́).