21. O kò gbọdọ̀ fa èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ kalẹ̀ fún lílò níbi ìbọ̀rìṣà Moleki, kí o sì ti ipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọrun rẹ jẹ́. Èmi ni OLUWA.
22. O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni.
23. O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni.
24. “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́.
25. Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde.