49. Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu,
50. yóo pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀ lórí odò tí ń ṣàn,
51. yóo mú igi Kedari ati ewé hisopu ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà, ati ẹyẹ keji, tí ó wà láàyè, yóo tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí ó pa lórí odò tí ń ṣàn, yóo wọ́n ọn sára ilé náà nígbà meje.
52. Bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà ati omi tí ń ṣàn, ati ẹyẹ tí ó wà láàyè, ati igi Kedari, ati ewé hisopu, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà sọ ilé náà di mímọ́ pada.
53. Yóo ju ẹyẹ náà sílẹ̀ kí ó lè fò jáde kúrò ninu ìlú, lọ sinu pápá, yóo fi ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilé náà, ilé náà yóo sì di mímọ́.”
54. Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni òfin tí ó jẹmọ́ oríṣìíríṣìí àrùn ẹ̀tẹ̀ ati ti ẹ̀yi ara;
55. ati ti àrùn ẹ̀tẹ̀ lára aṣọ tabi lára ilé,
56. ati ti oríṣìíríṣìí egbò, ati oówo, ati ti ara wúwú, tabi ti aṣọ tabi ilé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bò,
57. láti fi hàn bí ó bá jẹ́ mímọ́, tabi kò jẹ́ mímọ́. Àwọn ni òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀.