14. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi yìí, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́.
15. Alufaa yóo mú ninu ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀.
16. Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje.
17. Alufaa yóo mú ninu òróró tí ó kù ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.
18. Alufaa yóo fi òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.