34. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́.
35. Ṣugbọn bí àrùn ẹ̀yi yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí i tàn káàkiri lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́,
36. kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀yi náà bá ti gbilẹ̀ lára rẹ̀, kí alufaa má wulẹ̀ wò bóyá irun rẹ̀ pọ́n tabi kò pọ́n mọ́, aláìmọ́ ni.
37. Ṣugbọn bí ẹ̀yi yìí bá ti dáwọ́ dúró, tí irun dúdú ti bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ọ̀gangan ibẹ̀, ẹ̀yi náà ti san, ẹni náà sì ti di mímọ́. Kí alufaa pè é ní mímọ́.
38. “Bí ibìkan lára ọkunrin tabi obinrin bá déédé ṣẹ́ funfun,