6. “Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, kì báà ṣe fún ọmọkunrin tabi fún ọmọbinrin, yóo mú ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan wá sí ọ̀dọ̀ alufaa ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ fún ẹbọ sísun, kí ó sì mú yálà ọmọ ẹyẹlé tabi àdàbà wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
7. Alufaa yóo sì fi rúbọ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù fún un; nígbà náà ni yóo di mímọ́ kúrò ninu ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òfin yìí wà fún obinrin tí ó bá bímọ, kì báà jẹ́ ọmọkunrin ni ó bí tabi ọmọbinrin.
8. “Bí kò bá ní agbára láti mú aguntan wa, kí ó mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ekeji fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, yóo sì di mímọ́.”