27. Jaareṣaya, Elija ati Sikiri.
28. Àwọn ni baálé baálé ní ìdílé wọn, ìjòyè ni wọ́n ní ìran wọn; wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.
29. Jeieli, baba Gibeoni, ń gbé ìlú Gibeoni, Maaka ni orúkọ iyawo rẹ̀.
30. Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu;
31. Gedori, Ahio, Sekeri, ati
32. Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.
33. Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.
34. Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.
35. Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi.