29. Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká.Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.
30. Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera.
31. Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti.
32. Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua.
33. Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu.
34. Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu.
35. Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali.
36. Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira;
37. Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera.
38. Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara.