8. Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,
9. Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.
10. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
11. Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;
12. Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.
13. Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya,
14. Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki.