71. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.
72. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati;
73. Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
74. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni;
75. Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
76. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
77. Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari.Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
78. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa,