Kronika Kinni 6:25-31 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ọmọ meji ni Elikana bí: Amasai ati Ahimotu.

26. Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati;

27. Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana.

28. Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji.

29. Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei,

30. Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya.

31. Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ;

Kronika Kinni 6