10. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
11. Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;
12. Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.
13. Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya,
14. Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki.
15. Jehosadaki lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Ọlọrun jẹ́ kí Nebukadinesari wá kó Juda ati Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.
16. Àwọn ọmọ Lefi ni: Geriṣoni, Kohati ati Merari.
17. Àwọn ọmọ Geriṣoni ni: Libini ati Ṣimei.
18. Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli.
19. Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili ati Muṣi. Àwọn ni baba ńlá àwọn ọmọ Lefi.
20. Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Geriṣoni nìwọ̀nyí: Libini ni baba Jahati, Jahati bí Sima,
21. Sima bí Joa, Joa bí Ido, Ido bí Sera, Sera sì bí, Jeaterai.
22. Àwọn tí ó ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kohati nìwọ̀nyí: Aminadabu ni baba Kora, Kora ló bí Asiri;
23. Asiri bí Elikana, Elikana bí Ebiasafu, Ebiasafu sì bí Asiri.