20. Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
21. Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú.
22. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.
23. Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni.