1. Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.
2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu).
3. Àwọn ọmọ Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu, ni: Hanoku, Palu, Hesironi ati Kami.
4. Joẹli ni ó bí Ṣemaya, Ṣemaya bí Gogu, Gogu bí Ṣimei;
5. Ṣimei bí Mika, Mika bí Reaaya, Reaaya bí Baali;
6. Baali bí Beera, tí Tigilati Pileseri ọba Asiria mú lẹ́rú lọ; Beera yìí jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà Reubẹni.
7. Àwọn arakunrin rẹ̀ ní ìdílé wọn, nígbà tí a kọ àkọsílẹ̀, ìran wọn nìyí: olórí wọn ni Jeieli, ati Sakaraya, ati
8. Bela, ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli, tí wọn ń gbé Aroeri títí dé Nebo ati Baali Meoni.