7. Noga, Nefegi, ati Jafia,
8. Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti,
9. Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.
10. Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati;
11. Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi;
12. Amasaya, Asaraya, ati Jotamu;
13. Ahasi, Hesekaya, ati Manase,
14. Amoni ati Josaya.
15. Orúkọ àwọn ọmọ Josaya mẹrẹẹrin, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn ni: Johanani, Jehoiakimu, Sedekaya ati Ṣalumu.
16. Jehoiakimu bí ọmọ meji: Jekonaya ati Sedekaya.
17. Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli,