Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.