Kronika Kinni 23:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli.

2. Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ.

3. Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000).

Kronika Kinni 23