Kronika Kinni 22:16-19 BIBELI MIMỌ (BM)

16. àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti idẹ, ati ti irin. Bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nisinsinyii! Kí OLUWA wà pẹlu rẹ!”

17. Dafidi pàṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli pé kí wọ́n ran Solomoni, ọmọ òun lọ́wọ́.

18. Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀.

19. Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.”

Kronika Kinni 22