8. Etani ni ó bí Asaraya.
9. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.
10. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda,
11. Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi,
12. Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.
13. Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea;
14. Netaneli ati Radai;
15. Osemu ati Dafidi.