Kronika Kinni 2:29-31 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un.

30. Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú.

31. Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.

Kronika Kinni 2