1. Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni;
2. Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri.
3. Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á.
4. Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera.
5. Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli.
6. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada.