Kronika Kinni 16:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ,tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan,tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀,

20. tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji,láti ìjọba kan sí òmíràn,

21. kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

22. Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!”

23. Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé!Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ.

24. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan!

25. OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ.

26. Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun,ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run.

27. Ògo ati agbára yí i ká,ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀.

28. Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé,ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́!

29. Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un,ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀!Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́,

30. ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé,ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae.

31. Kí inú ọ̀run kí ó dùn,kí ayé kí ó yọ̀,kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”

Kronika Kinni 16