Kronika Kinni 12:8 BIBELI MIMỌ (BM)

Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè.

Kronika Kinni 12

Kronika Kinni 12:2-10