Kronika Kinni 1:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani,

10. Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé.

11. Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu;

12. àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito.

13. Àkọ́bí Kenaani ní Sidoni, lẹ́yìn rẹ̀ ó bí Heti,

14. Kenaani yìí náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Girigaṣi;

15. àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki ati àwọn ará Sini;

Kronika Kinni 1